Jona 2

Getting your Trinity Audio player ready…

Adura Jona

1 NIGBANA ni Jona gbadura si Oluwa Ọlọrun rẹ̀ lati inu ẹja na wá,

2 O si wipe, Emi kigbe nitori ipọnju mi si Oluwa, on si gbohùn mi; mo kigbe lati inu ipo-okú, iwọ si ti gbohùn mi.

3 Nitoriti iwọ ti sọ mi sinu ibu, larin okun; iṣàn omi si yi mi kakiri; gbogbo bibì omi ati riru omi rẹ kọja lori mi.

4 Nigbana ni mo wipe, A ta mi nù kuro niwaju rẹ; ṣugbọn sibẹ emi o tun ma wo iha tempili mimọ́ rẹ.

5 Omi yi mi kakiri, ani titi de ọkàn; ibu yi mi kakiri, a fi koriko-odò wé mi lori.

6 Emi sọkalẹ lọ si isalẹ awọn oke nla; ilẹ aiye pẹlu idenà rẹ̀ wà yi mi ka titi: ṣugbọn iwọ ti mu ẹmi mi wá soke lati inu ibú wá, Oluwa Ọlọrun mi.

7 Nigbati o rẹ ọkàn mi ninu mi, emi ranti Oluwa: adura mi si wá sọdọ rẹ sinu tempili mimọ́ rẹ.

8 Awọn ti nkiyesi eke asan kọ̀ ãnu ara wọn silẹ.

9 Ṣugbọn emi o fi ohùn idupẹ rubọ si ọ; emi o san ẹjẹ́ ti mo ti jẹ. Ti Oluwa ni igbala.

10 Oluwa si sọ fun ẹja na, o si pọ̀ Jona sori ilẹ gbigbẹ.

0 0 votes
Article Rating

Leave a Reply

0 Comments

Discover more from Welcome to facenotee👍🏿

Subscribe now to keep reading and get access to the full archive.

Continue reading

0
Would love your thoughts, please comment.x
()
x