Isaiah 12 yoruba

Orin Ọpẹ́

1 ATI li ọjọ na iwọ o si wipe, Oluwa, emi o yìn ọ: bi o tilẹ ti binu si mi, ibinu rẹ ti yi kuro, iwọ si tù mi ninu.

2 Kiyesi i, Ọlọrun ni igbala mi; emi o gbẹkẹle, emi ki yio si bẹ̀ru: nitori Oluwa Jehofah li agbara mi ati orin mi; on pẹlu si di igbala mi.

3 Ẹnyin o si fi ayọ̀ fà omi jade lati inu kanga igbala wá.

4 Li ọjọ na li ẹnyin o si wipe, Yìn Oluwa, kepe orukọ rẹ̀, sọ iṣẹ́ rẹ̀ lãrin awọn enia, mu u wá si iranti pe, orukọ rẹ̀ li a gbe leke.

5 Kọrin si Oluwa: nitori o ti ṣe ohun didara: eyi di mimọ̀ ni gbogbo aiye.

6 Kigbe, si hó, iwọ olugbe Sioni: nitori ẹni titobi ni Ẹni-Mimọ́ Israeli li ãrin rẹ.

Leave a Reply

Discover more from Welcome to facenotee👍🏿

Subscribe now to keep reading and get access to the full archive.

Continue reading