Deuteronomi 25

1 BI gbolohùn-asọ̀ kan ba wà lãrin enia, ti nwọn si wá si ibi idajọ, ti nwọn si dajọ wọn; nigbana ni ki nwọn ki o fi are fun alare, ki nwọn ki o si fi ẹbi fun ẹlẹbi;

2 Yio si ṣe, bi ẹlẹbi na ba yẹ lati nà, ki onidajọ na ki o da a dọbalẹ, ki o si mu ki a nà a ni iye kan li oju on, gẹgẹ bi ìwabuburu rẹ̀.

3 Ogoji paṣan ni ki a nà a, kò gbọdọ lé: nitoripe bi o ba lé, ti o ba si fi paṣan pupọ̀ nà a jù wọnyi lọ, njẹ arakunrin rẹ yio di gigàn li oju rẹ.

4 Máṣe di akọ-malu li ẹnu nigbati o ba npakà.

Ojúṣe Ẹni sí Arakunrin Ẹni Tí Ó Ṣaláìsí

5 Bi awọn arakunrin ba ngbé pọ̀, ti ọkan ninu wọn ba si kú, ti kò si lí ọmọkunrin, ki aya okú ki o máṣe ní alejò ara ode li ọkọ: arakunrin ọkọ rẹ ni ki o wọle tọ̀ ọ, ki o si ní i li aya, ki o si ṣe iṣẹ arakunrin ọkọ fun u.

6 Yio si ṣe, akọ́bi ọmọ ti o bi ki o rọpò li orukọ arakunrin rẹ̀ ti o kú, ki orukọ rẹ̀ ki o má ba parẹ́ ni Israeli.

7 Bi ọkunrin na kò ba si fẹ́ lati mú aya arakunrin rẹ̀, njẹ ki aya arakunrin rẹ̀ ki o gòke lọ si ẹnubode tọ̀ awọn àgba lọ, ki o si wipe, Arakunrin ọkọ mi kọ̀ lati gbé orukọ arakunrin rẹ̀ ró ni Israeli, on kò fẹ́ ṣe iṣẹ arakunrin ọkọ mi.

8 Nigbana ni awọn àgba ilu rẹ̀ yio pè e, nwọn a si sọ fun u: bi o ba si duro si i, ti o si wipe, Emi kò fẹ́ lati mú u;

9 Nigbana ni aya arakunrin rẹ̀ yio tọ̀ ọ wá niwaju awọn àgba na, on a si tú bàta rẹ̀ kuro li ẹsẹ̀ rẹ̀, a si tutọ si i li oju; a si dahùn, a si wipe, Bayi ni ki a ma ṣe si ọkunrin na ti kò fẹ́ ró ile arakunrin rẹ̀.

10 A o si ma pè orukọ rẹ̀ ni Israeli pe, Ile ẹniti a tú bàta rẹ̀.

Àwọn Òfin Mìíràn

11 Bi awọn ọkunrin ba mbá ara wọn jà, ti aya ọkan ba si sunmọtosi lati gbà ọkọ rẹ̀ lọwọ ẹniti o kọlù u, ti on si nawọ́ rẹ̀, ti o si di i mú li abẹ:

12 Nigbana ni ki iwọ ki o ke ọwọ́ rẹ̀ kuro, ki oju rẹ ki o máṣe ṣãnu fun u.

13 Iwọ kò gbọdọ ní onirũru ìwọn ninu àpo rẹ, nla ati kekere.

14 Iwọ kò gbọdọ ní onirũru òṣuwọn ninu ile rẹ, nla ati kekere.

15 Iwọn pipé ati dẽde ni ki iwọ ki o ní; òṣuwọn pipé ati dẽde ni ki iwọ ki o ní: ki ọjọ́ rẹ ki o le pẹ ni ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ.

16 Nitoripe gbogbo ẹniti nṣe wọnyi, ati gbogbo ẹniti nṣe aiṣododo, irira ni si OLUWA Ọlọrun rẹ.

Òfin láti Pa Àwọn Ará Amaleki

17 Ranti ohun ti Amaleki ṣe si ọ li ọ̀na, nigbati ẹnyin nti ilẹ Egipti jade wá;

18 Bi o ti pade rẹ li ọ̀na, ti o si kọlù awọn ti o kẹhin rẹ, ani gbogbo awọn ti o ṣe alailera lẹhin rẹ, nigbati ãrẹ mú ọ tán, ti agara si dá ọ; ti on kò si bẹ̀ru Ọlọrun.

19 Nitorina yio si ṣe, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba fun ọ ni isimi lọwọ gbogbo awọn ọtá rẹ yi ọ ká kiri, ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní lati ní i, ki iwọ ki o si pa iranti Amaleki rẹ́ kuro labẹ ọrun; iwọ kò gbọdọ gbagbé.

Diutaronomi 26

Ọrẹ Ìkórè

1 YIO si ṣe, nigbati iwọ ba dé ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní, ti iwọ si gbà a, ti iwọ si joko ninu rẹ̀;

2 Ki iwọ ki o mú ninu akọ́so gbogbo eso ilẹ rẹ, ti iwọ o mú ti inu ile rẹ wá, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ; ki iwọ ki o si fi i sinu agbọ̀n, ki iwọ ki o si lọ si ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si.

3 Ki iwọ ki o si tọ̀ alufa na lọ ti yio wà li ọjọ́ wọnni, ki o si wi fun u pe, Emi jẹwọ li oni fun OLUWA Ọlọrun rẹ, pe emi wá si ilẹ na ti OLUWA bura fun awọn baba wa lati fi fun wa.

4 Ki awọn alufa ki o si gbà agbọ̀n na li ọwọ́ rẹ, ki o si gbé e kalẹ niwaju pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ.

5 Iwọ o si dahùn iwọ o si wi niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ pe, Ara Siria kan, ti o nṣegbé ni baba mi, on si sọkalẹ lọ si Egipti, o si ṣe atipo nibẹ̀, ti on ti enia diẹ; nibẹ̀ li o si di orilẹ-ède nla, alagbara, ati pupọ̀:

6 Awọn ara Egipti si hùwabuburu si wa, nwọn si pọn wa loju, nwọn si dì ẹrù wuwo rù wa:

7 Awa si kepè OLUWA, Ọlọrun awọn baba wa, OLUWA si gbọ́ ohùn wa, o si wò ipọnju wa, ati lãlã wa, ati inira wa:

8 OLUWA si mú wa lati Egipti jade wá pẹlu ọwọ́ agbara, ati apa ninà, ati pẹlu ẹrù nla, ati pẹlu iṣẹ-àmi, ati pẹlu iṣẹ-iyanu:

9 O si mú wa dé ihin yi, o si fi ilẹ yi fun wa, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.

10 Njẹ nisisiyi, kiyesi i, emi mú akọ́so ilẹ na wa, ti iwọ, OLUWA, fi fun mi. Ki iwọ ki o si gbé e kalẹ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ki iwọ ki o si ma foribalẹ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ:

11 Ki iwọ ki o si ma yọ̀ ninu ohun rere gbogbo, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ati fun ara ile rẹ, iwọ, ati ọmọ Lefi, ati alejò ti mbẹ lãrin rẹ.

12 Nigbati iwọ ba da idamẹwa asunkun rẹ tán li ọdún kẹta, ti iṣe ọdún idamẹwa, ti iwọ si fi fun ọmọ Lefi, alejò, alainibaba, ati opó, ki nwọn ki o ma jẹ li ẹnubode rẹ, ki nwọn si yó;

13 Nigbana ni ki iwọ ki o wi niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ pe, Emi ti mú ohun mimọ́ kuro ninu ile mi, mo si ti fi wọn fun ọmọ Lefi, ati fun alejò, ati fun alainibaba, ati fun opó, gẹgẹ bi gbogbo aṣẹ rẹ ti iwọ ti pa fun mi: emi kò re aṣẹ rẹ kọja, bẹ̃li emi kò gbagbé wọn:

14 Emi kò jẹ ninu rẹ̀ ninu ọ̀fọ mi, bẹ̃li emi kò mú kuro ninu rẹ̀ fun ohun aimọ́ kan, bẹ̃li emi kò mú ninu rẹ̀ fun okú: ṣugbọn emi ti gbà ohùn OLUWA Ọlọrun mi gbọ́, emi si ti ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti iwọ palaṣẹ fun mi.

15 Wò ilẹ lati ibujoko mimọ́ rẹ wá, lati ọrun wá, ki o si busi i fun Israeli enia rẹ, ati fun ilẹ na ti iwọ fi fun wa, bi iwọ ti bura fun awọn baba wa, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.

Àwọn Eniyan OLUWA

16 Li oni OLUWA Ọlọrun rẹ paṣẹ fun ọ lati ma ṣe ìlana ati idajọ wọnyi: nitorina ki iwọ ki o ma pa wọn mọ́, ki iwọ ki o si ma fi gbogbo àiya rẹ ati gbogbo ọkàn rẹ ṣe wọn.

17 Iwọ jẹwọ OLUWA li oni pe on ni Ọlọrun rẹ, ati pe iwọ o ma rìn li ọ̀na rẹ̀, iwọ o si ma pa ìlana rẹ̀ mọ́, ati aṣẹ rẹ̀, ati idajọ rẹ̀, iwọ o si ma fetisi ohùn rẹ̀:

18 OLUWA si jẹwọ rẹ li oni pe iwọ o ma jẹ́ enia ọ̀tọ fun ara rẹ̀, bi on ti ṣe ileri fun ọ, ati pe iwọ o ma pa gbogbo aṣẹ rẹ̀ mọ́;

19 On o si mu ọ ga jù orilẹ-ède gbogbo lọ ti o dá, ni ìyin, li orukọ, ati ọlá; ki iwọ ki o le ma jẹ́ enia mimọ́ fun OLUWA Ọlọrun rẹ, bi o ti sọ.

Leave a Reply

Discover more from Welcome to facenotee👍🏿

Subscribe now to keep reading and get access to the full archive.

Continue reading